Spread the love

Iran asa Kan kii ta ni Koro, Adelabu gbangba lasa’ta.

O ti da ifa , ifa re fo’re. Ire Ni ifa re n fo lati ile IRA to fi de Ire, irenimogun omo awuko gbinrin bi enida agoogo ide, to fi de ile Ibadan ilu Ajayi o gbori Efon sa gilagila. ati ibi gbogbo tojumo ba tii n mo.

Ofun meji nifa re da, o ni- “Obarabogbe gbogbo bayi lowo ma n yo ju Ori, gbogbo Ni orunkun fi n tayo popolo itan. Gbogbo Ni mariwo n yo ju ope. Iwo lo ma yo ju gbogbo won lo.

O tun n wipe “Iran Keke Ni leke igi, awon iran osibata a leke odo. Iwo lo ma a leke ninu ibo to n bo”.  Adelabu wa n yin Awo, awo n yinfa, ifa n yin adaniwaye, oba ateni forigbeji.  Ase n tedumare.

Awon alufa abewu gereje naa o gbeyin won ni ” Abdulwaheed Adelabu ti di Kaaba ti ko see ri sa.  Awon onigbagbo agbaye ti di odi mu fun o, won ni adura re ti gba, ope lo ku ti iwo yoo ma da. Ope Ni pe Ni saye awo ilobi, iyin nii fun ni niyi awo Ewi…..

Ilufemiloye loruko to ye o
Teteregun re ti lomi tele kojo o to de. Omo adara nibi, omo adaranijo, omo omo Akande iji to n se omo hunmaani , ida meji Ibadan ti awon alsimokan n pe lenikan loke oluokun.
Adelabu Adegoke to se falejo- to se fonile.

Te jeje o, inu Jin, opa Moose ko le to ja, omo Adelabu, eni a bii re , to Ni inu rere, to tun Lori rere, to tun mu iwa rere mo, Pele lejo n gun agbon , eso Pele ni ohun ti o n wa a to e lowo.  Bi won n bu o, ma wo be, akokoro lo n yo won lenu. Maro Maro lo n se won bi orogun oka. Iwo SA ja kainkain boti, ki o fi won pegi.

See also  Group Rallies Support For Folarin As 9th Assembly DSP

Iwo kii se oloselu to fe teba si Efo ilu, iwo lomo alowo sile keebo to de. Ife ilu lo mu o ya soselu, ki Tara ile, ta ra oko le mu  owo ifa bonu. Ki ohun gbogbo le wa ni yutun- yugba. Eleda mekunnu a gbe o nija. Igba eke Ni fowo ti ile.

O gbo ohun ti onilu n wi ndan? Se ko si eni to mo ede ayan bi eni mu opa e lowo, eni to mu omele dani, lo mo ohun ti o n tenu omole Jade. Ilu n dun ,Orin tele, ka ma da muso Ayo fun Adebayo lo ku. Ilu naa ye mi, ki se afoyegbe, Orin naa ye mi, ki se afoyeko.

O ni: “Won o ba a nawo , nawo ki won donigbese, owo omo Adelabu lo maa bo si. “

“Iwe ti won ko ko ko, ti no won o sun, ti won o wo, owo omo Adelabu lo maa bo si. “

Adelabu Penkelemesi, mesi, mesi, Penkelemesi.

Adelabu Adebayo ipinle  Oyo n reti re, wa mu wa re ipele tokan.

https://www.highcpmrevenuegate.com/pw77e8xa?key=c5fbc1cd17a43e1458688e6496ffa538