ÀGBÀAKIN Pàràkòyí Ilẹ̀ Ìbàdàn tó tún jẹ́ olùdíje fún ipò Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lábẹ́ àsìá ẹgbẹ́ òsèlú APC nínú ìbò ọjọ́ kẹsàn-án osù kẹta, ọdún 2019 ti kí gbogbo ọmọlẹ́yìn Krístì kúu pọ̀pọ̀sìnsìn ayẹyẹ ọdún Àjíǹde tó ń lọ lọ́wọ́.
Nínú àtẹ̀jáde tí wọ́n fi sọwọ́ sáwọn oníròyìn níìlú Ìbàdàn, èyí tí amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ nípa ètò ìròyìn, Ọ̀mọ̀wé Báyọ̀ Búsàrí síì fọwọ́sí, Olóyè Adélabú rọ àwọn ọmọ Nàìjíríà lápapọ̀, pàápàá jùlo, àwọn èèyàn Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ láti túbọ̀ fara won jìn fún ìlọsíwájú orílẹ̀-èdè yìí fún ìgbáyégbádùn t’olórí t’ẹlẹ́mù.
GẸ́GẸ́ bí àtẹ̀jáde náà se sọ, Jésù Krístì se ìgbọràn sí ìfẹ́ Ọlọ́run Alágbára nípa fífi ara rẹ̀ rúbo kí àgbàríjọ ọmọnìyàn baà le ní ìyè àìnípẹ̀kun.
“NÍDÌÍ èyí, gbogbo ọmọlẹ́yìn Krístì gbódọ̀ wo àwòkọ́se ìfaraẹnijì àti ìwà ìrẹ̀lẹ̀ èyí tí Jésù Olùgbàlà fi kọ́ wa nínú gbogbo ìsesí àti ìgbé ayé rẹ̀.
“ORÍLẸ̀-ÈDÈ wa, àti pàápàá jùlọ, Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ nílò l’ọ́kùnrin àti l’óbìnrin ọmọ ilẹ̀ yìí tí yóò farajì láti leè ri pé t’olórí t’ẹlẹ́mù gbé ìgbé ayé tó n’ítumọ̀ gẹ́gẹ́ bíi ẹnikọ̀ọ̀kan bá se lágbára tó.
IṢẸ́ takuntakun tó wà níwájú gbogbo àwa ọmọ orílẹ̀-èdè yìí nílò ìfọwọ́sowọ́pọ̀ t’olórí t’ẹlẹ́mù láìfi t’ẹ̀sìn tàbí t’ẹ̀yà se kí èròǹgbà ìjọba ti Ààrẹ Muhammadu Buhari ń se adarí rẹ̀ baà le gbé orílẹ̀-èdè yìí dé ilẹ̀ ìlérí.” Àtẹ̀jáde náà fi àwọn ọ̀rọ̀ yìí mulẹ̀.
OLÓYÈ Adélabú kò sàì gba gbogbo ẹlẹ́sìn Krìstìẹ́nì Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ níyànjú láti túbọ̀ máa lépa àlàáfíà gẹ́gẹ́ bí ìjọba tó wà lórí àlèéfà lọ́wọ́lọ́wọ́ se fi lé’lè.