Spread the love

NI asaale ojo Aiku, ogbonjo osu kejila odun 2018 ni eto ori redio Petals FM ohun waye. Laago mejo si aago mewa ni eto olosoose Igbesi Aye ohun gori afefe ti gbogbo ara ilu si n teti leko. Ori eto naa to jemo oro oselu Oni batani iforowanilenuwo naa ni *Ogbeni Maestro*, iyen Atokun eto ati awon ara ile to n gbo redio ti n takoto okan o jokan awon ibeere si Alejo Pataki lale ojo naa.

ALEJO Pataki  ori eto lojo naa si ni Oludije fun Ipo Gomina Ipinle Oyo labe Asia Egbe APC, Oloye Abdul-Waheed Adebayo Adekola Adelabu. Bo tile je pe aago mejo abo ale ojo naa ku die ni Oloye Adelabu to gori afefe, amo logan ti Omo Penkele menu le oro ni gbogbo awon to n gbo eto oselu naa ti mo pe Oludije labe Asia Egbe APC naa ti gbaradi fun ise nla to fee teri si gege bi Gomina Ipinle Oyo lodun 2019!

AMO koko kan gbogi to jeyo ninu awon oro ti Atokun eto, Ogbeni  Maestro takoto re sita ni bi idagbasoke ati ilosiwaju Ipinle Oyo yoo se ya kanmokanmo. Olootu eto woye pe ninu gbogbo Oludije fun Ipo Gomina, aseyori ati awon igbega Oloye Adebayo Adelabu lo fee ya ju laarin won! Nigba ti Atokun n dari eto, Ogbeni Maestro beere pe bawo ni Alejo Pataki ohun se se to fi je pe laarin odun mejidinlaadota to ti lo laye, fere bi ekun ni awon okan o jokan aseyori Oloye Adelabu. Koda, Atokun eto naa woye pe yato si pe irin ajo Oludije Egbe APC naa ya,  awon aseyori Oloye Adelabu tun gontio, o koja ajanaku mo ri nnkan firi!

GEGE bi olopolo pipe ti Oloye Adebayo Adelabu n se, omo Penkele ni looto ni pe o dabii pe irin ajo oun ya, eyi to mu ki oun tayo pupo ninu awon Oludije si Ipo Gomina yooku. Onimo isiro owo ati gbogbo eto to jemo inawo naa tun salaye pe itepamose, ibowo fagba, ise takuntakun lai sinmi ati lai saare ati ju gbogbo re lo, aanu ati oore ofe Olorun Oba Alawurabi lo gbe oun de ibi ti oun de loni! Oloye Adelabu salaye siwaju si pe bo tile je wipe won bi oun si inu ebi to loruko rere, oun gege bii ‘Bayo omo Adelabu ko kan joko kale repete, kawo bo’tan o. O ni pelu itosona ati iranlowo Olorun, nise ni oun tun ara oun bi nipa titepa mose lai se imele, pelu ibowo fun gbogbo awon Oga oun gbogbo. Oloye Adelabu kadii re nile pe idi niyen ti alubarika ati aseyori se n tele oun kaakiri titi to fi di akoko yii!

“NJE kin waa ni idi tabi  afojusun Oloye Adebayo Adelabu to fi waa ro pe wiwo agbami eto oselu ni oro oun kan nipa kikowe fi ipo Igbakeji Gomina Banki Apapo Ile wa Naijiria (CBN) sile? Atokun Eto ohun lo n bi Oloye Adelabu leeree bee o! Idahun Odomokunrin Oludije naa si ree; “Bi Olorun Oba Oga Ogo ba ti gbadura eeyan debi to lapere, o maa n di igba kan ti eeyan gbodo maa ro pe kinni mo le se lati m’aye derun fun gbogbo ara ilu. Erongba ati ife lati mu ki gbogbo mutumuwa, tolori telemu ati opo eeyan to ku die kaato fun lawujo naa gbe igbe aye alaafia ati se anfaani loke eepe lo mu mi teri si agbami oselu lai bikita awon ewu ati wahala to wa nibe.” Oloye Adebayo Adelabu tun salaye siwaju, o ni; ” To ba je ti idakaa ka jeun aladidun, wo aso to joju ni gbese, gbe ile alarinrin awosifila, pelu awon ipo ati aseyori to giriki lawujo, mo dupe pe Olorun Oga Agba ti gbadura mi tayoo mimoose temi nikan. Amo nitori erongba ati ife lati ri pe ogooro awon eeyan Ipinle Oyo naa janfaani ijoba awarawa ati jijegbadun awon ohun amayederun bii ti awon oyinbo alawo funfun ile okeere lo gbemi wo agbami oselu!”

EYI to wa pabanbari ninu awon alaye oro to jade lenu Oludije labe Asia Egbe APC lori eto ori redio Petals FM naa ree. *Oloye Adelabu so wipe bi oun se ri aanu Eledumare gba to fi ya oun kankan lati de ipo Oga nla ni gbogbo ibi ti oun ti sise  ati aseyori ninu igbesi aye oun lapapo, bee ni ife ati erongba oun Abdu-Waheed Adebayo omo Adelabu Penkelemeesi naa se ri lati mu idagbasokee kiakia ati kanmo-n-kobo ba gbogbo Ipinle Oyo ati tolori telemu ti won je omo ati ara ipinle naa!

See also  Halilu Targets First Quarter 2024 To Put NASENI Products In Nigeria Market

SE enu onikan la tii gbo poun, bi Penkelemeesi se salaye oro naa funraa re ree; “E seun gan. Atokun. Eyin naa ti woye funraa yin pe o maa n yami kiakia  lati se aseyori ninu gbogbo ise ti mo ba dawole tabi ise oojo ti mo  yan laayo ati awon ise ilu ti mo ba lanfaani lati se.  Iruu sura, oore ofe ati aseyori bee eyi ti Olorun maa n fun mi se ni mo ni erongba lati gbe wo eto isejoba Ipinle Oyo nibi ti idagbasoke, ilosiwaju ati igbayegbadun alailegbe yoo ti ba tolori- telemu, tokunrin-tobinrin, tonile-talejo, tomode-tagba ati gbogbo mutumuwa kaakiri tibu-tooro ati  jakejado Ipinle Oyo lagbara Olorun. Ni kukuru, mo fe ki gbogbo eeyan Ipinle Oyo lee tete maa jegbadun eto isejoba awarawa ni kiakia ju ti tele lo. Mo mo pe bi Olorun Alaanu se se edaa mi ti aseyori mi fi maa n ya, bee naa ni Olorun Oba O ni dawoduro ti Yoo fi bami dari ijoba naa ti aseyori ati igbayegbadun yoo fi ba Ipinle Oyo ati awon eeyan inu re ni kanmo-n-kobo ati ni kiakia nigba ti a ba de ipo Gomina pelu atileyin gbogbo ara ilu ati ase Olorun Oba!”

PELU alaye ti Oloye Adebayo Adelabu se soke yi, o fi han wipe Oludije Gomina labe Asia Egbe APC yi mo oun to n so. Oju mo ohun to yonu, idodo nidaji ara, ipenpeju si ni opin fila! Bi opo o tile ba’tan, tolori telemu lo ba aroba baba itan Adegoke Adelabu Penkelemeesi babaa baba Adebayo Adelabu. Ninu Itan ati akosile, alaseyori ponbele ti ko fee si elegbe re ni Adelabu nigba ayee re ninu oselu orile ede Naijiria. Laarin odun mejilelogoji pere ti Adegoke Adelabu se loke eepe, tibutooro orile ede Naijiria  yi ni won ti gboruko Penkelemeesi Agba fun orisirisi ise rere to se ninu eto oselu ko too sile bora bi aso ni odun 1958!

See also  ADELABU, ALLI, OMODEWU, SHITTU'S BILLBOARDS DEFACE.

ITUMO gbogbo asamo oro waa ni pe omo Ajanaku kii yara, omo tekun ba bi ekun ni o jo. Iyen ni wipe gbogbo awon aseyori ti Adebayo Adelabu ti se yi, Omo Penkele ba nile ni! A  je pe bi Penkelemeesi kan ba ku ni 1958, Penkelemeesi mii tun ku ti yoo bo si ipo Gomina ni 2019 bi a ba wo sakun bi oro ibo Gomina ti yoo waye lojo keji, osu keta odun 2019 naa se n lo bayi! Won ni a ii wi sibe, ka ku sibe. Koda, Ogbeni Maestro, Atokun Eto ale ojo naa menu ba, o si tun fo lena lori eto ori redio naa pe  o ti n jo pe odo Adelabu Penkele ni ewe olubori esi idibo naa fee ja si. Iyen ni pe ooto oro ko ni ka ma so oun!

OPO oro o kagbon, afefe lo n gbe lo! Orisirisi awon oro to jemo bi Oloye Adebayo Adelabu yoo se se ijoba ti yoo se gbogbo eeyan Ipinle Oyo lanfaani to ba dori aleefa lo jeyo lori Eto *Igbe Aye* to waye ni ori redio Petals FM lale ojo Aiku ta n wi yii. Lara awon akitiyan Oludije si Ipo Gomina labe Asia Egbe APC lati gbegba oroke nibi ibo to n bo naa si ni o fi lo si ori redio ohun l’ale ojo naa.Pelu wipe ogunlogo to poju ninu awon oludibo Ipinle Oyo lo fee fibo gbe Adelabu wole, ojoojumo ni Oludije ohun tubo n lo kaakiri lati polongo awon eto amayederun to ni fun awon ara ilu. Ohun to fa eyi ni pe gege bi ise Oloye Adelabu lateyinwa ninu ohunkohun to ba je logun, Oludije fun Ipo Gomina Egbe APC naa ko joko tetere lasan. Eredi gbogbo awon akitiyan Penkele wonyi si ni igbagbo re ninu akosile awon iwe Olorun to f’idii re mule pe “Okan alaapon lemi o mu sanra!”

See also  Oyo APC Stalwart, Bolaji Gbengbeleku Congratulates Folarin On 60th Birthday 

ABALO ababo ati gbogbo iwosakun oro yi tumo si pe Oba Alasepe ati  Alaseyori ni Olorun ti Adebayo omo Adelabu n sin lateyinwa. Edumare Oba Alawurabi ti o si fi Abdul-Waheed Adebayo Adelabu omo Adegoke Adelabu Penkelemeesi sile t’O fi n satileyin aseyori fun l’ateyinwa kO nii fi sile lasiko yi to fee se ife gbogbo ara ilu titi ti yoo fi gori aleefa gege bii  Gomina Ipinle Oyo lodun 2019 yii!

Akinsola Ige je onwoye ati onkowe lori awon oro to n lo lawujo. Ibadan ni Arakunrin naa fi se ibugbe.

https://www.highcpmrevenuegate.com/pw77e8xa?key=c5fbc1cd17a43e1458688e6496ffa538